AAJO EWA NILE YORUBA LAYE ATIJO ATI LODE ONI

ISORI KIN-IN-NI

IDI TI MO FI FE SE ISE LORI AAJO EWA NILE YORUBA LAYE ATIJO ATI LODE ONI

          Orisirisi ona ni awon onimo ti gba lati se ise tabi lati se iwadii lori ona ti a n gba lati se aajo ewa pataki laarin awon Yoruba sugbon pupo ninu won ni ko tu isu de isale ikoko nipa fifi itumo tabi ona ti a n gba se aajo ewa ni ile Yoruba, eyi lo mu mi fe se ise naa ni ona ti awon baba nla n gba lati se aajo ewa laye atijo ki o to dip e asa awon oyinbo gbode.

Ni ona keji ewe mo fe lati je ki o han si awon odo tabi ewe iwoyi pe ko leto lati fi owo ro asa ile wa seyin nitori asa oyinbo ti o gbode kan, ti o n je ki awon odo bu enu ate lu awon asa naa, ti a ba ri eniti o ko ila tabi ti o wo aso bi ti atijo won le fi enu sata onitohun pe ko rookan, idi ti o si fi ri bee nip e won ko mo irufe iyi tabi anfani ti o wa nibe. Sugbon mo fe se ise naa ni ona ti yoo gba fi iwulo tabi anfani ti o wa nipa ewa sise ni aye atijo.

PATAKI AAJO EWA NILE YORUBA LAYE ATIJO ATI LODE ONI

          Aajo ewa je ona ti a ngba lati bu ewa kun ara wa, o tun je ona ti a n gba lati se orisirisi oso si ara wa ni ireti pe yoo bu kun ewa ara wa.

Gege bi a ti mo pea won Yoruba je eya kan ti won feran lati maa se ewa tabi oge si ara won ti a ba fe wo pataki ewa sise a o wo orisirisi ona ti a gba n mura ni aye ara wa.

Ti a ba n se ifobaje tabi ifinijoye ni ile Yoruba a o rip e orisirisi imura ni awon eniyan yoo mu paapaa awon oba tabi awon ti won fe je oye naa, awon aso ti o gba iyi ileke ati bata ileke pelu irukere funfun lowo won, awon iyawo won gan-an ko gbeyin orisirisi irun ara ni won a di ti won yoo to ileke si, won a wo aso oke ti o gbaju pelu ileke ni orun ati owo won.

Awon ti o ba je eru oba ti a mo si ilari yoo fa irun apakan won a fi apa kan sile.

Ni ona miran ewe awon Yoruba gbadun lati maa se orisirisi oso tabi ewa si eya ara won ni pa sise ise ona si ara won eleyii wopo laarin awon obinrin, nitori bi obinrin ba se bu ewa kun ara re ni won yoo se buyi fun lawujo.

Ila kiko naa tun ko ipa pataki ninu ewa sise ni akoko awon baba nla wa won n loo lati fi iyato han laarin eya kan si ekeji ati lati fi mo awon ti o je ibatan nigba ti ogun ti ya won.

Siwaju si lilo awon ohun eso ara bii ileke, yeri eti ati irun sise laarin obinrin ko gbeyin orisirisi asa ni awon obinrin n fi irun da sugbon gige ni awon okunrin ge irun won orisirisi ona ni won le fi gee.

How to get complete project materials


Step 1: make payment of N3000 to any of the bank below


NAME:                       TITUS AYANI SOLA
BANK:                       FIRST BANK PLC
ACCT NO:                  3111741042
ACCOUNT TYPE:       SAVINGS
AMOUNT:                  N3000

NAME:                       TITUS AYANI SOLA


BANK:                       WEMA BANK
ACCT NO:                  0237422220

STEP 2: AFTER PAYMENT SEND THE PROJECT TOPIC AND YOUR MODE OF DELIVERY (EMAIL ADDRESS OR WHATSAPP) TO 08063666753

Updated: 22nd June 2017 — 11:23 am